Man City vs Brighton ratings Goal.com

Ìgbájú Ìgbàmú ni Brighton fi bá Manchester City jà Pẹ̀lú Góòlù Méjì Sí Òkan

Last Updated: August 31, 2025By Tags: , ,

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City kò rí ọ̀nà àbáyọ lónìí ní ilé Brighton bí wọ́n ṣe jẹ góòlù méjì sí òkan (2-1) nínú ìdíje Premier League ìpele kẹta lónìí.

Erling Haaland, atamatasé Man City, ni ó kọ́kọ́ fi àmì ayò kan wọlé fún City láti ṣáájú nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n èyí kò fún wọn ní ìṣẹ́gun bí olùdárí eré ìdíje náà ṣe pè fún ìdálẹ́bi kan ní àgbègbè Man City.

James Milner ló gba àmì ayò kan wọlé láti fi àmì ayò dọ́gba fún Brighton pẹ̀lú bọ́ọ̀lù ìfìyàjẹ (Penalty) kan ní ìlàjì àkókò kejì.

Man City vs Brighton ratings Goal.com

Man City vs Brighton ratings Goal.com

Brajan Gudars náà ló gba àmì ìkejì wọlé fún Brighton láti gba ìṣẹ́gun lórí City ní ìṣẹ́jú àyá kan dín-láàdọ́rún (89th) pẹ̀lú bọ́ọ̀lù tí ó gbá tí asọ́lé Man City kò lè mú.

Pep Guardiola kò borí nínú gbogbo àwọn ìpàdé mẹ́ta tó bá Fabian Hürzeler ṣe ní Premier League.

Olùdarí kan ṣoṣo tí ó kojú ní ìgbà mẹ́ta tí wọn kò sì borí ni Ronald Koeman (P3 D2 L1).

Brighton wá láti ẹ̀yìn láti ṣẹ́gun Manchester City 2-1 ọpẹ́lọpẹ́ góòlù tí James Milner àti Brajan Gruda gbá.

Àkọsílẹ̀ tí Rodri ṣe ní Premier League ní ìgbà 49 tí ó ti bẹ̀rẹ̀ láìsí ìṣẹ́gun ti dópin

Ní báyìí, City wà ní ipò kẹtàlá (13th) lórí tábìlì ìdíje náà lẹ́yìn tí wọ́n ti ra oríṣiríṣi agbábọ́ọ̀lù ní ìgbà ìyágbálẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n wọn kò ní àǹfàní láti ṣẹ́gun nínú ìdíje méjì.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment