Ibon Adeògùn (Arsenal) ló padà kan wọn lẹ́sẹ̀ lónìí, tí wọ́n padà nìkàn rìn ní Anfield óòóò!
Ó máa ṣee oò, Ibon Adẹ́ògùn (Arsenal) ló padà kan wọn lẹ́sẹ̀ lónìí, tí wọ́n padà nìkàn rìn ní Anfield óòóò!
Lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó gbóná janjan, Arsenal padà rìn nìkan lóòkankan óò, lẹ́yìn tí Liverpool fi ìyà jẹ wọ́n pẹ̀lú àmì ayò kan ṣoṣo ní Anfield.
Ṣé ni ó dà bí ẹni pé, àmì òdo sí òdo (0-0
) ni wọn ó máa gbà bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ eré ìdíje bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá náà pẹ̀lú gbá-sími kí n gbá sí o.
Mikel Arteta ṣà gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé ó tayọ, ṣùgbọ́n gbogbo kìràkìtà wọn, pápá ló já sí bí Liverpool ṣe sọ pé: “Ìyẹ̀ẹ̀ kan ni ẹ óò máa wò, ẹ ò lè rí adìyẹ wá pa oò!”
Arsenal gba bọ́ọ̀lù bí ìgbà tí wọ́n fẹ́ kú, ṣùgbọ́n ó ṣe ni láàánú pé, ìgbìyànjú wọn kò já sí àṣeyọrí nígbà tí asọ́lé Liverpool sọ pé “òní kọ́, ẹ padà wá lọ́la”.
Pẹ̀lú gbogbo ẹni bi Calafiori, Eze, Madueke, Timber, àti Caliber tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal ni, wọ́n kùnà láti ṣe àṣeyọrí lónìí.
Dominik Szoboszlai fi ọ̀pá ìbọn tarata Arsenal kan wọ́n lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú bọ́ọ̀lù tí ó gbà láti ibi ìwọ̀n ọ̀fẹ́ (Free Kick) ní ìṣẹ́jú mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83rd
).
Akonímọ̀gbá Arsenal ṣe àtúnṣe mẹ́ta kíákíá láti rí i pé kí ó lè dọ́gba àmì ayò náà, ṣùgbọ́n kò sí àyè fún wọn.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal ti pàdánù àyò kan ṣoṣo láti ìbẹ̀rẹ̀ ìdíje yìí, ibo ni wọn ò parí sí?
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua