Ibo Ipinle Osun, Adeleke ko lo jawe Olubori L’odun 2022

Last Updated: July 22, 2025By Tags: , , ,

Aṣofin atijo ni ekun Osun-East Senatorial District, Sẹnetọ Babajide Omoworare , ni ọjọ Aje ti so erongba rẹ lati dije du ipo gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun 2026 lori pẹpẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).

Nigba to n soro nibi akowe egbe APC to wa niluu Osogbo, Omoworare bu enu ate lu Gomina Ademola Adeleke ati egbe oselu PDP, o si n tenumo pe egbe oselu PDP ko jawe olubori ninu ibo gomina lodun 2022, sugbon o kan je anfaani ninu rogbodiyan laarin egbe APC ni.

Omoworare, eni to ti je oludamoran pataki fun Aare nigba kan ri lori oro ofin so pe ijakule egbe oselu APC ninu idibo to koja lo je funra re.

O ni, “Adeleke ati PDP ko jawe olubori ninu ibo ni Osun lodun 2022, APC padanu e latari ija laarin won, sugbon a ko nii pada si ibomii mo, mo wa lati ran wa lowo lati yege.”

O ṣakiyesi pe iyapa ati awọn ẹdun ọkan ti ko yanju laarin awọn ipo ẹgbẹ ti pese aaye ti o dara fun PDP lati lo.

Nigba to n fi han awon asaaju egbe ati awon alatileyin nipa erongba re lati di gomina, Omoworare so pe oun ko tii jawe olubori rara ati pe oun ni igboya pe oun yoo mu isegun fun egbe APC.

Omoworare ni, “Emmarun ni mo ti dije, mi o si tii jawe olubori, koda nigba ti won fee da mi yo ni mo lo si kootu, ti mo si jawe olubori, pelu ore-ofe Olorun, oga agba irawo marun-un ni mi ninu oselu.

Omoworare, eni to darapo mo idije naa lori eto egbe All Progressives Congress (APC), tun fi iwe afihan re han fun awon olori egbe, o si seleri lati da egbe naa pada sipo.

Nigba to n ba Alaga egbe naa soro, Tajudeen Lawal atawon omo egbe naa, Omoworare so pe oun ko tii jawe olubori rara, ati pe oun n pada si ibi isele naa pelu okun tuntun lati tun ipinle Osun tun se.

“Emi ni itesiwaju de mojuto, Baba nla mi ni ‘Afenifere’ Baba iya mi, Ooni ti Ife ni gomina akoko ni Western Region, oselu wa ninu eje mi, PDP ko gba Osun, APC padanu re, sugbon a ko ni padanu mo, mo wa lati ran wa lowo lati se atunse.”

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment