Gómìnà Uzodimma Kéde Àfikún sí Owó Oṣù N104,000 àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Imo, Sẹ́nétọ̀ Hope Uzodimma, ti kéde àfikún pàtàkì nínú owó oṣù kéré jù lọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní ìpínlẹ̀ náà, tí ó fi í ga sí ọgọ́rùn-ún le mẹ́rin ẹgbẹ̀rún náírà N104,000.
Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn Nàìjíríà (NAN) ròyìn pé wọ́n fi àfikún kún owó oṣù kéré jù lọ náà láti N76,000 sí ọgọ́rùn-ún le mẹ́rin ẹgbẹ̀rún náírà N104,000.
Gómìnà náà ṣe ìkéde yìí nígbà ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ náà tí ó wáyé ní Ilé Ìjọba ní Owerri.
Nípasẹ̀ ìgbésẹ̀ kan náà, àfikún ti wà nínú owó oṣù àwọn dókítà ní iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà, ó sì ti di N582,000 lóṣooṣù.
Gómìnà Uzodimma ṣàlàyé pé àfikún owó oṣù náà ṣeé ṣe nípasẹ̀ àfikún nínú owó tí ìpínlẹ̀ náà ń kó wọlé àti àfikún nínú ìpín owó láti ìjọba àpapọ̀.
Ó tẹnu mọ́ ọn pé ètò ìsanwó tuntun náà jẹ́ láti mú ọrọ̀ ajé Ìpínlẹ̀ Imo kún, láti sì fi àyè gba ìṣòdágbàsókè ìfẹ́ àti agbára iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba.
Gómìnà Uzodimma tún kéde Naira bílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún láti fi san owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n jẹ àwọn tó ti fẹ̀yìntì ní ìpínlẹ̀ náà.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua