Ghana

Ghana Se Ìsìnkú Ìjọba fún Àwọn Ènìyàn Mẹ́jọ Tí Wọ́n Kú Nínú Ìjàmbá Ọkọ̀-òfuurufú

Ghana ti se ìdágbére ìkẹ́yìn fún àwọn ènìyàn mẹ́jọ tí wọ́n kú nínú ọ̀kan lára àwọn ìjàmbá afẹ́fẹ́ tí ó burú jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá.

Ìṣẹ̀lẹ̀ búburú náà wáyé nígbà tí ọkọ̀-òfuurufú oní-ìyẹ́-èjìká ti àwọn ológun tí ó gbe àwọn aláṣẹ ìjọba àti àwọn òṣìṣẹ́ padà kúrò lára ẹ̀rọ àkọsílẹ̀ ní kété lẹ́hìn tí ó jáde láti Accra, olú-ìlú.

Àwọn tí ó wà nínú rẹ̀ ni Mínísítà Ọ̀rọ̀ Ìgbèjà, Edward Omane Boamah, Mínísítà Ọ̀rọ̀ Ayíká, Ibrahim Murtala Muhammed, àwọn èrò mẹ́rin mìíràn, àti àwọn òṣìṣẹ́ méjì.

Ọkọ̀ náà n lọ sí ìlú tí wọ́n ti n wa wúrà, ìyẹn Obuasi ní Agbègbè Ashanti nígbà tí ó ṣubú, ó sì mu emi gbogbo eniyan mẹ́jọ náà.

Nínú ìsìn-ìrántí ti orílẹ̀-èdè, Ààrẹ John Dramani Mahama yìn àwọn tí wọ́n kú náà, ó sì se ìlérí àtìlẹ́yìn fún àwọn ẹbí wọn.

Ó sọ pé: “Lónìí, mo fẹ́ se ìkéde àwọn ìpinnu ìjọba láti bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́-ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn wọnyìí àti láti se ìdánilójú ọjọ́-ọ̀la àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀,” “Mo béèrè pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ fún ẹ̀mí àánú tí ó jẹ́ àmì orílẹ̀-èdè wa fún àwọn ẹbí tí ó banújẹ́ wọnyìí.”

Ìdí ìjàmbá náà wà lábẹ́ ìwádìí síbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ pé ìkùukù tó pọ̀ wà ni agbègbè náà ni àkókò tí ọkọ̀-òfuurufú náà padà. Wọ́n ti gbà àwọn àpótí dúdú ti ọkọ̀ náà padà láti ibi ìjàmbá náà, àwọn aláṣẹ ọkọ̀-òfuurufú sì n se ìgbélèsè lórí rẹ̀ láti mọ̀ ohun tí ó se.

Ìparun náà ti se ìdààmú ńlá káàkiri orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ìyìn tí ó n wọlé láti àwọn ẹ̀ka ìṣèlú. Àwọn àsíá wà lórí ìdá-méjì káàkiri orílẹ̀-èdè bí àwọn ará Ghana se dúró fún ìgbà díẹ̀ láti rántí àwọn ẹ̀mí tí ó sọ nù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yìí.

Orisun – Africanews

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment