Sophie Vouzelaud, ni eni akoko to tele Omidan Franxe ni odun 2007- Wireimage lati Getty Images

Ẹni tí wọ́n fi ìwà ìjìbìtì ifẹ́ orí Íntánẹ́ẹ̀tì tan rin Ìrìn-àjò ọgọ́rùn-ún méje kìlómítà láti lọ fẹ́ ayaba ẹwà ilẹ̀ Faransé

Last Updated: July 18, 2025By Tags: , ,

Ọkùnrin kan ọmọ orílẹ̀-èdè Bẹ́líjíọ̀mù ti rin ìrìn-àjò kilomita 760 (milẹ 472) láti pàdé obìnrin kan tí ó jẹ́ àmì ẹwà orílẹ̀-èdè Faransé, tí wọ́n ti fi mú un gbàgbọ́ pé yóò di aya rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ṣùgbọ́n ó wá rí i nígbà tó dé pé òun ti di àjẹ́nirun ìwà ìjìbìtì ifẹ́ orí Íntánẹ́ẹ̀tì.

Michel, ẹni ọdún méje ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin, lọ sílé Sophie Vouzelaud nílẹ̀ Faransé, ọkọ obìnrin náà ló sì bá a.

Ó sọ fún Fabien ọkọ Vouzelaud pé òun ti san €30,000 ($35,000) fún àwọn onijìbìtì náà, òun sì rò pé òun ti wà nínú ìbáṣepọ̀ ifẹ́ fún ọ̀sẹ̀ díẹ̀.

Nígbà tí ọkùnrin náà ń ronú nípa bí wọ́n ṣe máa rin ìrìn àjò náà pa dà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ò rí i pé arìndìn ni mí”.

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tí Michel ṣe di mímọ̀ lẹ́yìn tí fídíò kan tí ó fi ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ tí ó ní pẹ̀lú tọkọtaya náà hàn, tí Fabien pín lórí ayélujára.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀, ọmọ Belgium – tí ó ti di opó láti ọdún mẹ́rin sẹ́yìn – ti ń bá ẹni tí ó rò pé ó jẹ́ Ms Vouzelaud, tí ó jẹ́ Miss Limousin tẹ́lẹ̀, tí ó sì jẹ́ oludije àkọ́kọ́ fún Miss France ní ọdún 2007 sọ̀rọ̀ lórí WhatsApp.

Ó farahàn lode ilé tọkọtaya náà ní Saint-Julien, tí ó jìn ní nǹkan bí 420km (milẹ 270) sí gúúsù Paris, ní Oṣù Keje ọjọ́ 9, gẹ́gẹ́ bí Fabien ti sọ, ó sì wí pé: “Èmi ni ọkọ Sophie Vouzelaud ní ọjọ́ iwájú,” èyí tí Fabien fi dá a lóhùn pé: “Ó dára, èmi ni èyí tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́.”

Ìyáàfin Vouzelaud, ẹni ọdún mẹ́jidínlógójì, wá gbìyànjú láti ṣàlàyé fún un pé wọ́n ti tan jẹ, tọkọtaya náà sì rọ̀ ọ́ pé kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá láti lọ fi ẹ̀sùn kan wọlé. A ò mọ̀ bóyá ó ṣe bẹ́ẹ̀.

Jìbìtì ifẹ́ jẹ́ nígbà tí wọ́n bá tan ènìyàn jẹ́ láti fi owó ránṣẹ́ sí ọ̀daràn kan tí ó mú wọn gbàgbọ́ pé wọ́n wà nínú ìbáṣepọ̀ tòótọ́.

Orisun- BBC

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment