Èmi Ni Olórin Tí Rihanna Fẹ́ràn Jù Lọ – Ayra Starr
Akọrin ọmọ Nàìjíríà, Ayra Starr, ti sọ pé ó ṣe àṣàyàn tó dára nípa yíyan Rihanna gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe orin rẹ̀.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tuntun pẹ̀lú ETalk TV, Starr ṣàpèjúwe Rihanna gẹ́gẹ́ bí “ẹni àrà ọ̀tọ̀ àti ẹni tí èèyàn lè wòran.” Ó rántí ìgbà àkọ́kọ́ tó ti pàdé Rihanna, tí gbajúgbajù olórin náà sì sọ fún un pé òun fẹ́ràn orin rẹ̀.
Starr fi hàn pé ohun tó mú inú òun dùn jù lọ nípa ìpàdé náà ni rírí i pé òun ni olórin tí olórin ayanfẹ́ òun fẹ́ràn jù lọ. Ó sọ pé, “Òun [Rihanna] jẹ́ èèyàn àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, ó [ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀] ṣì dàbí àlá. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Àwọn èèyàn máa ń sọ pé, ‘máṣe pàdé àwọn àwòkọ́ṣe rẹ láé’, ṣùgbọ́n inú mi dùn gan-an pé mo pàdé tèmi nítorí pé ó jẹ́ èèyàn àrà ọ̀tọ̀ lásán. Àti pé òun fẹ́ràn orin mi; èmi ni olórin tí olórin ayanfẹ́ mi fẹ́ràn jù lọ. “Ó jẹ́ olórin àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀, obìnrin àrà ọ̀tọ̀, èèyàn àrà ọ̀tọ̀ lápapọ̀; ẹni tí èèyàn lè wòran. Mo mọ̀ pé mo yan àwòkọ́ṣe tó dára, àti pé nígbà tí mo bá wà ní àyíká rẹ̀, mi ò sábà mọ ohun tí màá fi ara mi ṣe. Nígbà tí mo bá bẹ̀rù ní àyíká rẹ̀, màá máa gbìyànjú láti ṣe àwàdà tí kò pọn dandan.”
Orísun: Daily Post
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua