EFCC Kéde Pé Won Wá Sujimoto
Ìgbìmọ̀ Àjọ tí ó ń rí sí Ètò Ìsúnná-owó àti Ọ̀ràn-ajé Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (EFCC) ti kéde Olasijibomi Suji Ogundele, tí a mọ̀ sí Sujimoto Luxury Construction Limited, pé a ń wá a káàkiri lónìí, Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kárùn-ún, Oṣù Kẹsan, Ọdún 2025, nítorí ẹ̀sùn ìwádìí lórí ìyípadà owó sí ọ̀nà mìíràn àti fífọ owó dudu.
Gbólóhùn yìí tí a fi sórí ìkànnì òṣìṣẹ́ wọn ní X lónìí ní òwúrọ̀, sọ pé ọkùnrin ọmọ ọdún 44 (44
) tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Ìjọba Ìbílẹ̀ Ori-Ade ní Ìpínlẹ̀ Osun ni ìpìlẹ̀ rẹ̀, àti pé ibi tí a gbẹ̀yìn mọ̀ pé ó ń gbé ni: G 29, Banana Island, Ikoyi, Ìpínlẹ̀ Èkó.
Wọ́n rọ àwọn ará ìlú tí ó bá ní ìròyìn kankan nípa rẹ̀, láti fi sọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ wọn ní èyíkéyìí nínú àwọn ọ́fíìsì wọn káàkiri orílẹ̀-èdè.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua