EFCC, Àjọ Àbò ti Àwọn Ará Ìlú Da ọmọ ilẹ̀ òkèèrè Mọ́kànléláàdọ́ta Pada Sí ile Wọn Lórí esun jìbìtì orí ayélujára
Àjọ Tí Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ajé àti Ìwà-Ọ̀daràn (EFCC) àti Àjọ Àbò Àtijọ́ ti Àwọn Ará Ìlú (NIS) ti tún fi àwọn ènìyàn òkèrè mọ́kànléláàdọ́ta (51) mìíràn pada sí ile wọn, tí wọ́n ti dá lẹ́bi, tí wọ́n sì ti fi ìdájọ́ lé wọn lórí fún ìwà-ọ̀daràn lórí ayélujára.
Àwọn ènìyàn òkèrè tí wọ́n fi padà sí ilẹ̀ wọn jẹ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China àdọ́ta (50) àti ọmọ orílẹ̀-èdè Tunisia kan.
Ìfipadà tuntun yìí ti mú kí gbogbo iye àwọn ènìyàn òkèrè tí wọ́n ti dá lẹ́bi, tí wọ́n sì ti lé kúrò ní orílẹ̀-èdè, jẹ́ ọgọ́rùn-ún àti méjì (102) nínú ìgbòkègbodò tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Jímọ̀, Oṣù Kẹjọ Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, ọdún 2025.
Àwọn tí wọ́n dá lẹ́bi wà lára àwọn ènìyàn òkèrè igba ó din mejo (192) tí àjọ tí ó ń dojú ìjà kọ ìwà ìbàjẹ́ fi ọgbọ́n mú ní ìlú Èkó, lẹ́yìn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ àjọ ilẹ̀ òkèrè kan nípa iṣẹ́ ìwà-ọ̀daràn lórí ẹ̀rọ-ayélujára tí ó gbòòrò ní Nàìjíríà.
Àwọn tí wọ́n lé kúrò wà lára àwọn ènìyàn 759 tí EFCC fi ọgbọ́n mú ní àkókò ìgbòkègbodò ńlá kan ní Oṣù Kejìlá Ọjọ́ kẹwàá, ọdún 2024, ní òpópónà Oyin Jolayemi, Victoria Island, ní Èkó.
Ẹgbẹ́ náà ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn lórí ẹ̀rọ-ayélujára àti ètò Ponzi
tí ó gbòòrò kí wọ́n tó fi ọgbọ́n mú wọn nínú ìgbòkègbodò apapọ kan.
Gẹ́gẹ́ bí EFCC, tí ó ṣe àkóso àwọn ìgbẹ́jọ́ náà, àpapọ̀ àwọn ènìyàn òkèrè 192—tí ó ní àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China àti Philippines—ni wọ́n dá lẹ́bi lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀tàn náà.
Nígbà tí wọ́n mú wọn wá sí ilé-ẹjọ́, àwọn olùwá-ìdájọ́ náà wá sí àwọn àdéhùn ìjẹ́wọ́ ẹ̀sùn pẹ̀lú EFCC.
Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìdájọ́ nínú àwọn ọ̀ràn wọn, àwọn onídàájọ́ náà dá wọn lẹ́bi ọdún kan nínú ẹ̀wọ̀n kọ̀ọ́kan, wọ́n sì paṣẹ pé kí wọ́n gbà àwọn ohun-ìní, àwọn ẹ̀rọ àti àwọn ohun ìní ẹ̀rọ-ayélujára tí wọ́n rí lọ́wọ́ wọn.
Àwọn Onídàájọ́ náà tún paṣẹ fún Olùdarí Àgbà ti Immigration láti rí i dájú pé wọ́n fi àwọn tí wọ́n dá lẹ́bi padà sí orílẹ̀-èdè ibi tí wọ́n ti wá láàárín ọjọ́ méje, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti lo ìgbà àtìmọ́lé wọn.
Wọ́n ti tún ṣètò àwọn ìfipadà mìíràn fún àwọn ọjọ́ tó ń bọ̀.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua