Dangote Dín Owó Ẹ̀pọ̀ Kù Sí ₦820 Lórí Lítà Kan

Last Updated: August 13, 2025By Tags: , ,

Ilé-iṣẹ́ Àpìtúnpọ̀ Ẹ̀pọ̀ ti Dangote ti kéde dídín owó àpìtúnpọ̀ (gantry) ti Epo Ọkọ̀ Alátìlẹyìn (PMS) kù, ní ₦30 láti ₦850 sí ₦820 lórí lítà kan.

Ìwé-ìkéde kan tí Olùdarí Àgbà fún Àwọn Ohun Ìjìṣẹ́ àti Ìbárasọ̀rọ̀, Anthony Chiejina, fọwọ́ sí, sọ pé àdínkù owó náà wáyé ni Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, oṣù kẹjọ, ọjọ́ kejila, ọdún 2025.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìkéde náà ṣe sọ, ìgbésẹ̀ náà jẹ́ apá kan ìfaramọ́ tí ilé-iṣẹ́ Àpìtúnpọ̀ Ẹ̀pọ̀ náà ní sí ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè, ó sì fi dá àwọn ará ìlú lójú pé ìpèsè àwọn ohun-èlò epo kò ní dáwọ́ dúró.

Ìwé-ìkéde náà fi kún un pé, “Ní ìbámu pẹ̀lú ìfaramọ́ wa sí ìṣesí tó dára àti àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé tó dúró ṣinṣin, Ilé-iṣẹ́ Àpìtúnpọ̀ Ẹ̀pọ̀ ti Dangote yóò bẹ̀rẹ̀ lílo àwọn ọkọ̀ 4,000 tí ó ń lo Compressed Natural Gas (CNG) fún pípín epo kiri ní gbogbo Nàìjíríà, ní oṣù kẹjọ, ọjọ́ kẹrindinlogun, ọdún 2025.”

 

Orisun – Channels

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment