Chelsea So PSG Di Ewure jele jele àti Àgùntàn tí ó ń jẹ nínú koríko
Chelsea fi PSG ṣe eléyà nínú àsẹ̀kágbá Ìdíje FIFA Club World Cup pẹ̀lú àyò ami mẹ́ta sí òdo.
Chelsea gba òyìnbó Ẹgbẹ́ tó dára jù lọ ní àgbáyé nínú ìdíje bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá FIFA Club World Cup lẹ́yìn tí wọ́n borí Paris Saint-Germain àmì àyò mẹ́ta sí òdo ní pápá ìṣeré METLIFE STADIUM NÍ AMERICA.
O fẹrẹ to oṣu kan ati idaji lẹhin ti o ṣẹgun UEFA Conference League, idije ipele kẹta ti Yuroopu, Chelsea ti gba ade FIFA Club World Cup!
Chelsea gba àmì ẹ̀yẹ yìí ní ọdún 2021 nígbà tí wọ́n na Palmeiras ní àmì àyò méjì sí òkan.
Ọmọ ìkọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea ni, Cole Palmer ló kọ́kọ́ fi omi kan wọlé ní ìṣẹ́jú méjìlélógún tí ó sì tún gba bọ́ọ̀lù kejì wọlé ní ìṣẹ́jú ọgbọ̀n.

Joao Pedro dunu boolu to gba wole X@chelseaFC
PSG gbìyànjú ṣùgbọ́n, aṣọlé Chelsea sọ pé “òní kò, bóyá kẹ́ padà wá ní ọjọ́ mìíràn” kó tó di pé ọmọ ìkọ̀ Chelsea tuntun fi omi àyò kẹta wọlé ní ìṣẹ́jú mẹ́tadínlógójì kí apá kìí eré náà tó parí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ Cole Palmer.
Akonímọ̀gbá Chelsea ṣe àtúntò àwọn agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ apá kejì bọ́ọ̀lù náà tí ó sì jẹ́ kí wọ́n di ilẹ̀ mú ṣinṣin kí PSG má bàa lè fi àmì kankan wọlé.
Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé, ìkọ̀ agbábọ́ọ̀lù PSG tó gbégbá orókè ní ìdíje UEFA Champions League náà gbìyànjú títí wọ́n fi gba káàdù pupa nígbà tí João Neves fa irun orí Cucurella ní orí pápá náà.
Ìdíje náà wáyé ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù keje ọdún 2025, lẹ́yìn tí PSG na Real Madrid láti dé Ìpele ìkẹyìn tí Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Chelsea na Fluminense pa.
Ǹjé wọ́n ní “bẹ́ẹ̀ni, ó bá tó ní kò yẹ ká yún sí ẹni”, PSG kò, wọ́n sọ pé àwọn tobẹ́ ṣùgbọ́n ìyà wọn dé ibi pé wọ́n kò lè rìn lọ ilé wọn.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua