Bayern Munich dana sun RB Leipzig Pẹ̀lú Àmì Àfojúsùn Góòlù Mẹ́fà sí Òdo
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Bayern Munich borí RB Leipzig FC nínú ìdíje àkọ́kọ́ wọn ní Bundesliga pẹ̀lú àmì àfojúsùn mẹ́fà sí òdo.
Ìdíje náà, tí wọ́n gbá lónìí ní papa-ìṣeré Alianz Arena, fi ìwàláyé tí Bayern ti fi ń na àwọn ọ̀tá wọn láìṣe àánú hàn, pẹ̀lú àmì àfojúsùn méjì láti ọ̀dọ̀ Michael Olise àti àmì àfojúsùn kan láti ọ̀dọ̀ agbábọ́ọ̀lù tuntun wọn láti Liverpool, Luiz Diaz.
Harry Kane, ní tiẹ̀, gbá àmì àfojúsùn mẹ́ta wọlé nínú ìdíje náà láti fi ìṣẹ́gun fún Bayern Munich, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Diaz àti Kim ní ìṣẹ́jú àádọ́rin ó lé méje nínú ìdíje náà.
Láti ìgbà tí Harry Kane ti dara pọ̀ mọ́ Bayern, ó ti gbá àmì àfojúsùn Bundesliga 63 wọlé, tó pọ̀ ju ti àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó gbajúmọ̀ ní Europe.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé VAR fagilé àmì àfojúsùn Leipzig nínú ìdíje náà lẹ́yìn ìyẹ̀wò, wọn kò lè dáhùn sí àwọn àmì àfojúsùn tí wọ́n jẹ lónìí.
Fún ìsinsìnyí, Bayern wà ní ipò àkọ́kọ́ lórí àtẹ ìdìbò Bundesliga pẹ̀lú ìyàtọ̀ àmì àfojúsùn mẹ́fà.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua