Àwọn Rọ́bọ́ọ̀tì Jà Nínú Eré ẹ̀ṣẹ́ Ní Àpérò Rọ́bọ́ọ̀tì Àgbáyé ti 2025

Àwọn Rọ́bọ́ọ̀tì Jà Nínú Eré ẹ̀ṣẹ́ Ní Àpérò Rọ́bọ́ọ̀tì Àgbáyé ti 2025

Àwọn rọ́bọ́ọ̀tì tí ó lè sáré, jó, tí wọ́n sì lè gbá bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá kò nìkan ni ohun tí ó jẹ́ àfojúsùn, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n lè pín àwọn nkan sílẹ̀ lórí ọ̀nà àwọn ohun-èlò, tí wọ́n sì lè kópa nínú eré mahjong àti bọ́ńkísì jẹ́ ohun àfojúsùn nìkan ní àwọn ìwé àtijọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n wà ní gbangba nínú àpérò World Robot Conference (WRC) tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní Beijing, orílẹ̀-èdè China.

Unitree Robotics, tí orí ilé-iṣẹ́ rẹ̀ wà ní Hangzhou, ní ìwọ̀-oòrùn China, ti mú àwọn irú rọ́bọ́ọ̀tì tuntun rẹ̀ tí ó ní ìrísí ènìyàn àti ẹsẹ̀ mẹ́rin wá síbi àfihàn yìí.

Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí ó fa àwọn ènìyàn mọ́ra ni eré bọ́ńkísì tí àwọn rọ́bọ́ọ̀tì GI tuntun méjì ṣe. Àwọn rọ́bọ́ọ̀tì náà ń gbá àṣáárá, wọ́n sì ń dáàbò bo ara wọn bí àwọn ènìyàn tòótọ́, wọ́n sì máa ń dìde lẹ́yìn tí wọ́n bá ti wó lulẹ̀.

Georg, olùdámọ̀ràn àwọn alákóso láti orílẹ̀-èdè Germany, sọ fún China News Service ni ọjọ́ Mọ́ńdè pé, “China ní àǹfààní ńlá nípa gbígbé àwọn irú rọ́bọ́ọ̀tì tuntun àti àwọn ohun-èlò ìṣèlò mìíràn jáde ní àkókò kúkúrú. Nítorí náà, mo nírètí pupọ fún ọjọ́ ọ̀la.”

Orisun – Africanews

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment