Contributory Pension Scheme (CPS)

Àwọn Olùfẹ̀yìntì Ìjọba Àpapọ̀ Láti Gba Àfikún N32,000 Oṣooṣù Lábẹ́ Àdéhùn CPS

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n ti fẹ̀yìntì lábẹ́ ìgbìmọ̀ ìfẹ̀yìntì ti Contributory Pension Scheme (CPS) ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gba àfikún N32,000 lórí owó oṣù ìfẹ̀yìntì wọn lẹ́hìn tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi ọwọ́ sí ọ̀kẹ́ àìmọ́ye owó N758 bíbílìọ̀nù láti fi san àwọn gbèsè owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n ti pẹ́ tí wọ́n ti jẹ.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ti sọ, àfikún owó yìí yóò jẹ́ ànfàní fún àwọn olùfẹ̀yìntì láti jàǹfààní lára òfin National Minimum Wage Amendment Act 2024 àti àwọn àtúnṣe tó tẹ̀lé e.

Yóò sì jẹ́ ìwọ̀n owó tí gbogbo àwọn olùfẹ̀yìntì ní àwọn ẹ̀ka ìṣẹ̀jọba bíi ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́, ètò ìlera, àwọn ajà-ilú, àti àwọn ọmọ ogun lábẹ́ CPS yóò gbà, láìka iye owó ìfowósílẹ̀ wọn sí.

Ààrẹ Tinubu, ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹjọ, pàṣẹ fún ìjọba rẹ̀ pé kí wọ́n máa san “àwọn ìyàtọ̀ owó ìfẹ̀yìntì àti owó ìdánilójú tó pẹ́ tipẹ́, láti lè pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn olùfẹ̀yìntì tó jẹ́ aláìní.”

Òṣìṣẹ́ kan ní National Pension Commission (PenCom) fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí Ilé-Ìgbimọ̀ Aṣòfin bá ti fi ọwọ́ sí i, owó ìdánilójú náà yóò wà fún gbígbàwọlé láìpẹ́.

Olùdarí-Àgbà PenCom, Omolola Oloworaran, ṣàlàyé pé owó N758 bíbílìọ̀nù yìí ni wọn yóò pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta: N253 bíbílìọ̀nù fún àwọn ẹtọ́ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kí CPS tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2004 tàbí àwọn tí wọ́n fẹ́ fẹ̀yìntì nígbà náà; N387.5 bíbílìọ̀nù láti san àwọn ìyàtọ̀ owó ìfẹ̀yìntì tí ó ti kù láti ọdún 2007; àti N107 bíbílìọ̀nù fún Pension Protection Fund, tí a dá sílẹ̀ láti fi kún owó ìfẹ̀yìntì fún àwọn tí owó iṣẹ́ wọn kéré.

Ó tẹnu mọ́ ọn pé ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì láti mú ìgbẹ́kẹ̀lé padà sí CPS, ó sì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ kan tó ti pẹ́ tí wọ́n ti fẹ́ ṣe láti yanju àwọn owó ìfẹ̀yìntì tí a kò san fún ìgbà ọdún méjì tí wọ́n ti pẹ́.

National Salaries, Incomes and Wages Commission (NSIWC) ti kéde àtúnṣe náà ní ọdún tí ó kọjá, wọ́n sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn olùfẹ̀yìntì yóò gba àfikún N32,000 ní gbogbo oṣù lábẹ́ ìlànà tuntun ti owó iṣẹ́. TVCnews

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment