Arsenal Signs Zubimendi

Arsenal Ti Parí Àdéhùn Pẹ̀lú Martin Zubimendi Láti Real Sociedad Fun Ogoota Mílíọ̀nù

Egbe Agbaboolu Arsenal ti parí àdéhùn pẹ̀lú Martin Zubimendi láti Real Sociedad nínú ìṣòwò tó fẹ́rẹ̀ tó £60 mílíọ̀nù.

Agbábọ́ọ̀lù àárín ti Spéìn yìí ni agbábọ́ọ̀lù kejì tí àwọn Gunners ti gbà wá ní àkókò ìṣíwọ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí, lẹ́yìn tí agbábọ́ọ̀lù tó máa ń gbèjà, Kepa Arrizabalaga, ti dé láti Chelsea fún £5 mílíọ̀nù.

Wọ́n tún ń bá Sporting sọ̀rọ̀ láti gbà ata matase ni Viktor Gyokeres wá fún £70 mílíọ̀nù.

Arsenal Signs Martin Zubimendi

Getty Image

Zubimendi, tó kọ ìpè láti darapọ̀ mọ́ Liverpool ní àkókò ooru tó kọjá, jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Real Sociedad látọ́dọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ kékeré wọn títí tó fi di olùkópa àkànṣe nínú ẹgbẹ́ àkọ́kọ́

Agbábọ́ọ̀lù àárín gbùngbùn ọmọ ọdún 26 (26-year-old) yìí  ẹni tí ó gbá bọ́ọ̀lù ní ẹ̀ẹ̀mẹ́rìndínlọogoji-lé-ní-igba (236) fún ẹgbẹ́ Spain náà, tó sì gbá bọ́ọ̀lù wọlé ní ẹ̀ẹ̀mẹ́wàá (10 goals)  ti fọwọ́ sí àdéhùn ọdún márùn-ún (five-year deal)

Zubimendi sọ pé: “Ìgbà yìí jẹ́ àkókò pàtàkì jùlọ nínú iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù mi. Èyí ni ìgbésẹ̀ tí mo ti ń wá, tí mo sì fẹ́ gan-an. Nígbà tí mo débí, mo mọ̀ pé ẹgbẹ́ yìí àti ilé-ìdíje yìí tóbi gan-an.

“Mo yàn Arsenal nítorí pé irú bọ́ọ̀lù tí wọ́n ń gba bá mi mu. Wọ́n ti fi agbára hàn lójú àgbáyé, mo sì mọ̀ pé ohun tó dára jùlọ ṣì ń bọ̀.

Ní àsìkò tó kọjá, Zubimendi wà lára ẹgbẹ́ tí wọ́n ṣẹ́gun 4-1 ní Old Trafford nígbà tí Sociedad, tí wọ́n parí ipò kọkànlá ní La Liga, jẹ́ kí Manchester United yọ wọ́n kúrò nínú ìdíje Europa League.

Ó ran orílẹ̀-èdè rẹ̀ lọ́wọ́ láti gba ife ẹ̀yẹ Euro 2024, nígbà tí ó wọlé fún Rodri ti Manchester City ní ìdajì àsìkò nínú ìdíje náà lòdì sí England nígbà tí góòlù Mikel Oyarzabal gba ife ẹ̀yẹ náà fún Spain.

Ó ti kógbá wọlé fún orílẹ̀-èdè Sípéènì ní ìgbà mọ́kàndínlógún, ó sì ti di òṣèré fún orílẹ̀-èdè Sípéènì látìgbà tí Rodri ti fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní sáà tó kọjá nítorí ọgbẹ́ orúnkún rẹ̀.

Zubimendi gba góòlù nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìdíje Nations League tó wáyé láìpẹ́ yìí lòdì sí orílẹ̀-èdè Potogí kí orílẹ̀-èdè Sípéènì tó pàdánù nínú ìdíje náà.

“Martin jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn àti ìmọ̀ nípa eré bọ́ọ̀lù wá fún ẹgbẹ́ wa”, ni ọ̀gá àgbà Arsenal, Mikel Arteta sọ.

“Ó máa bá wa lò dáadáa, ó sì ní gbogbo ànímọ́ tó máa mú kó di ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òṣèré wa. “Ipò tí ó ti wà látìgbàdégbà ní àwọn ọdún díẹ̀ tó kọjá fún ẹgbẹ́ àti orílẹ̀-èdè náà gan-an ni ìdí tí inú wa fi dùn láti ní i pẹ̀lú wa”.

Arsenal tún ti fọwọ́ sí àdéhùn pẹ̀lú Brentford láti gbà agbábọ́ọ̀lù àárín gbùngbùn, Christian Norgaard, wá fún £10 mílíọ̀nù ní ìbẹ̀rẹ̀.

Orisun: BBCNEWS

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment