eberechi-eze-crystal-palace - skysports

Arsenal Gbà Láti Ra Eberechi Eze Lẹ́yìn Tí Wọ́n gba Lọ́wọ́ Tottenham

Last Updated: August 21, 2025By Tags: , , ,

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Arsenal ti gbà láti san poun 67.5m fún ìṣòwò láti gba Eberechi Eze lẹ́yìn tí wọ́n ti yá ẹ̀mí wọlé sí ìṣòwò ìgbébọ́ọ̀lù tí ẹgbẹ́ Tottenham Hotspur ti fẹ́ ṣe pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù Crystal Palace náà.

Àwọn “Gunners” yóò san poun 60m tí a ti fọwọ́ sí pẹ̀lú poun 7.5m gẹ́gẹ́ bí owó àfikún, pẹ̀lú àwọn àdéhùn ti ara ẹni tí ó sún mọ́ pé a óò fọwọ́ sí i pátápátá báyìí.

Ìlànà tí ó lè jáde kúrò nínú àdéhùn ọmọ ọdún metadinlogbon náà, tí ó jẹ́ poun 60m pẹ̀lú poun 8m gẹ́gẹ́ bí owó àfikún, ti kọjá àkókò rẹ̀ kí ìdíje Premier League tó bẹ̀rẹ̀.

eberechi-eze-crystal-palace - skysports

eberechi-eze-crystal-palace – skysports

Sky Sports News gbọ́ pé ó ṣì nírètí láti wà nínú àwọn tí yóò wà nínú ẹgbẹ́ fún ìdíje Conference League tí Crystal Palace yóò gbá ní ọjọ́bọ̀, ó sì fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ àbọ̀ fún àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ náà.

Ẹgbẹ́ “Spurs” rò pé wọ́n ti wá sí àdéhùn pẹ̀lú Palace àti Eze ní ọjọ́rújú ṣáájú kí àwọn orògbó wọn ní àríwá London (Arsenal) tó tún ní ìfẹ́ sí i, tí wọ́n sì sáré wọlé lẹ́yìn ìgbà tí Kai Havertz fara pa.

Eze wà lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbábọ́ọ̀lù tí Arsenal wádìí ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ fún àyè ìgbébọ́ọ̀lù, níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ti wáyé ní oṣù kẹfà nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ipò ìṣòwò náà. Láti ìgbà náà, wọ́n ti dáwọ́ lé àwọn ipò mìíràn àti àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó fẹ́ kúrò ní ẹgbẹ́.

Eze, tí ó bẹ̀rẹ̀ ìdíje ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí Palace àti Chelsea ní ọjọ́ Àìkú, ní ọdún méjì tí ó kù nínú àdéhùn rẹ̀ ní Selhurst Park.

Ẹgbẹ́ Arsenalti ní ìfẹ̀ sí Eze tipẹ́tipẹ́, ẹni tí ó ti wà ní ilé ẹ̀kọ́ wọn tẹ́lẹ̀, tí ó sì ti sọ wípé òun ni alátìlẹyìn ẹgbẹ́ náà nígbà tí ó ń dàgbà.

Wọ́n ṣàyẹ̀wò àdéhùn kan ní ìbẹ̀rẹ̀ àyè ìgbébọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n wọ́n yàn láti má tẹ̀lé àdéhùn náà ní ìgbà yẹn nítorí wọ́n fi ànfàní sí mímú àwọn ipò mìíràn lágbára àti gbígba àdéhùn tuntun pẹ̀lú àwọn agbábọ́ọ̀lù tí ó wà ní ẹgbẹ́.

Lẹ́yìn náà ni ẹgbẹ́ “Spurs” wọlé fún Eze lẹ́yìn tí Morgan Gibbs-White yàn láti fọwọ́ sí àdéhùn tuntun ní Nottingham Forest àti wọ́n sì pàdánù James Maddison sí ìfarapa ACL.

Àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wáyé láàárín Tottenham àti Palace, àwọn “Spurs” sì rò pé wọ́n ti wá sí àdéhùn pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà àti agbábọ́ọ̀lù náà ní ọjọ́rújú.

Ṣùgbọ́n, ẹgbẹ́ Arsenal wọlé láti gbà àdéhùn náà ní ìyípadà pàtàkì ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rújú.

Orísun – Skysports

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment