APGA Jáwé Olúborí nínú Idibo fun Ile-Igbimo Asofin ni Anambra
Ẹgbẹ́-oṣelu All Progressives Grand Alliance (APGA) ti jáwé olúborí nínú idibo fun ipo Asofin Agbegbe Anambra South àti ti Ipinlẹ Onitsha North 1 tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ile-Iṣẹ Idibo Aladani ti Orilẹ-ede (INEC) polongo Oloye Emmanuel Nwachukwu gẹgẹ bi ẹni to wọlé fún Agbegbe Aṣòfin Anambra South, ati Barrister Ifeoma Azikiwe gẹgẹ bi ẹni to wọlé fún Onitsha North 1.
Nwachukwu gba ibo 90,408 lati bori Oloye Azuka Okwuosa ti ẹgbẹ́-oṣelu All Progressives Congress (APC), tó gba ibo 19,812, àti Donald Amamgbo ti African Democratic Congress (ADC), tó gba ibo 2,889.
Idibo náà, tí awọn ẹgbẹ́-oṣelu mẹ́rindínlógún (16) kópa nínú rẹ̀, ni wọ́n ṣe láti fi kún ibi òfo tó kù lẹ́yìn ikú Senato Ifeanyi Ubah.
Nwachukwu, ẹni tó jẹ́ Ààrẹ-Àgbà ti Ukpor Town Union tẹ́lẹ̀ rí ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Nnewi South, yoo jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti agbègbè náà tó yóò joko lori aga aṣòfin láti ìgbà tí ìjọba tiwa-n-tiwa tó wà lóde òní ti bẹ̀rẹ̀.
Ó tún jẹ́ aṣòfin APGA keji ní Ìpínlẹ̀ Anambra lẹ́yìn Senato Victor Umeh, tó ń ṣojú Agbegbe Aṣòfin Anambra Central lọwọlọwọ lábẹ́ ẹgbẹ́ Labour Party. Ní ilé-ìgbimọ̀ aṣòfin ní Abuja, òun yóò jẹ́ aṣòfin APGA kejì, níwọ̀n bí Senato Enyinnaya Abaribe tó ń ṣojú agbègbè Abia South nìkan ni ó wà lórí aga náà tẹ́lẹ̀ rí.
Àwọn Àbájáde Idibo Miiran àti Àwọn Iṣẹlẹ Tí Ó Selẹ̀
Ní agbègbè ilé ìgbimọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Onitsha 1, Azikiwe gba ìbò 7,774 láti bori Arabinrin Justina Azuka ti African Democratic Congress (ADC), tó gba ìbò 1,909. Azikiwe yóò jẹ́ obinrin kejì tó yóò wà nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́-ìgbimọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ tó tó ọgbọ̀n.
Obinrin tí ó jẹ́ olùdíje ADC ni opó fun aṣòfin tí wọn pa, Hon Justice Azuka, tí a rí òkú rẹ̀ nínú igbó ní nitosi afárá Second Niger Bridge ní Oṣù Keji ọjọ́ 6, ọdún 2025 lẹ́hìn tí wọ́n jí i gbé ni Efa Keresimesi ọdún 2024 ni Onitsha.
Ọ̀gbẹ́ni Ezennia Ojekwe ti All Progressives Congress (APC) àti Arabinrin Njideka Ndiwe ti Young Progressives Party (YPP) gba ìbò 1,371 àti 655 lẹ́sẹsẹ.
Aláṣẹ idibo náà, Ojogbọn Ibiam Ekpe ti Federal University of Technology, Owerri, tó polongo èsì ìbò náà, yin àwọn olùdíje àti àwọn olùdìbò fún ìwà àlàáfíà tí wọ́n fi hàn lásìkò ìdìbò náà.
Ikolu Lóri Igbakeji Gomina ati Komisona
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdìbò náà lọ dáadáa, kò ṣaláìní ìṣẹ̀lẹ̀ bíi pé Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Dr. Onyekachukwu Ibezim, àti Kọmíṣọ́nà fún Ayika, Engr. Felix Odumegwu, fi kùkùú sá fún ikú nígbà tí àwọn jàndùkú kọlù wọ́n ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Nnewi South.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Vanguard ṣe sọ, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n bínú dojúkọ Igbákejì Gómìnà náà, wọ́n sì dádúró fún ju wákàtí kan lọ lórí ẹ̀sùn pé ó ń ra ìbò. Wọn tún kọlù Kọmíṣọ́nà Odumegwu tó bá a lọ kí àwọn agbófinró tó wa gba won sílẹ̀.
Nígbà tí Gómìnà Chukwuma Soludo ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó fi ẹ̀sùn kan olùdíje Gómìnà fún All Progressives Congress (APC), Prince Nicholas Ukachukwu, pé òun ló l’ẹ́yìn ikọlù náà.
Gómìnà náà sọ pé, “Èyí jẹ́ ìwà ajàndùkú. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, pẹ̀lú Igbákejì Gómìnà àti Kọmíṣọ́nà fún Ayika, ni wọ́n kọlù. Ìwà yìí kò dára rárá.”
Akọ̀wé gbogboogbo ti orílẹ̀-èdè ti APGA, Mazi Ejimofor Opara, tún fi ẹ̀sùn kan Ukachukwu pé ó gbé àwọn jàndùkú láti da ìdìbò náà rú.
“Àwọn jàndùkú APC tí olùdíje wọn rán ni wọ́n kọlu Kọmíṣọ́nà fún Ayika. Tí kò bá ṣe fún àwọn agbófinró ní ìlú rẹ̀ ní Ezinifite, Aguata, ìṣẹ̀lẹ̀ náà iba ti burú jọjọ,” ni Opara sọ.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua