Amnesty international

Amnesty International Kéde fún Ìdádúró Lílo Agbaara Lodi sí Àwọn Olùwọ́de ní Orilẹ Ede Togo

Last Updated: July 4, 2025By Tags: ,

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan, tí wọ́n fi pamọ́ fún ọjọ́ márùn-ún ní àwọn àgọ́ ọlọ́pàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ọjọ́ márùn-ún, tí wọ́n sì ń fún ní àpò omi kan ṣoṣo lójoojúmọ́. Ọkùnrin kan, tí àwùjọ àwọn sójà gbéjà kò títí tó fi dákú. Àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí àwọn tí a kò mọ orúkọ wọn jí gbé.

Èyí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà ìkà tí wọ́n sọ pé àwọn tó ń ṣe àtakò ní Tógò ti fojú winá rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀rí tí àjọ Amnesty International kó jọ.

Reuters

Amnesty sọ ní Ọjọ́bọ̀ pé, àjọ náà ti kéde fún Togo láti fòpin sí lílo agbára “tó pọ̀ jù àti aláìnídí” lòdì sí àwọn olùwọ́de.

Àwọn ará ìlú ní olú-ìlú Lomé jáde sí òpópónà lòdì sí àwọn àtúnṣe òfin láìpẹ́ láti Oṣù Kẹfà Ọjọ́ Kẹrindinlogun sí ọjọ kejidinlogun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwọ́de ti wáyé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù Kẹfà.

Àwọn àtúnṣe wọ̀nyí lè fàyè gba Ààrẹ Faure Gnassingbé láti fa ìjọba rẹ̀ tó ti tó ogún ọdún lórí orílẹ̀-èdè náà gbòòrò sí i láìnídálẹ́kọ̀ọ́. Gnassingbé wá sípò lọ́dún 2005, ó tẹ̀lé bàbá rẹ̀, tí ó ti wà nípò fún ọdún mejidinlogoji (38).

Amnesty International sọ pé ó ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀ríẹ̀rí mẹ́tàlá tí ó ṣàlàyé irúfẹ́ lílo agbára àìtọ́ àti ìwà ìlòkulò láti ọwọ́ àwọn ọmọ ogun aabo àti ọlọ́pàá ní àwọn ìwọ́de wọ̀nyí.

Àwọn ìwọ́de Oṣù Kẹfà Ọjọ́ 26-28 fi ó kéré tán àwọn olùwọ́de meje sílẹ̀ tí wọ́n ti kú, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí wọ́n rí tí wọ́n ti kú ní adágún Bè, pẹ̀lú àwọn ọmọdé. Àwọn òkú kan ní àwọn ihò ìbọn wa lara wọn.

Gẹgẹbi awọn iroyin oriṣiriṣi, o kere ju awọn eniyan mẹfa ti o padanu emi re titi di Oṣù Keje Ọjọ́ Kejì.

Amnesty tún béèrè pé kí Togo gbe ìwádìí tó jinlẹ̀ kalẹ̀, kí wọ́n sì dáwọ́ ìlò agbára tó pọ̀ ju, kí ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè náà jẹ́ olóòtítọ́, kó sì ṣe ìtọju àwọn olùwọde ní ìlànà tó tọ́.

Orisun: Africanews

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment