Ààrẹ Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà, Akpabio, Kọ Àwọn Àhesọ Ilera Rẹ̀

Ààrẹ Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà, Akpabio, Kọ Àwọn Àhesọ Ilera Rẹ̀

Ààrẹ Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti Nàìjíríà, Godswill Akpabio, ti padà sí orílẹ̀-èdè lẹ́yìn ìsinmi kúkúrú kan ní ìlú Lọ́ńdọ̀nù.

Nígbà tí ó dé, ó kó àwọn àhesọ pé ó ní àìsàn líle tí wọ́n sì gbà á sí ilé ìwòsàn ní orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Sẹ́nátọ̀ Akpabio ti kọ́kọ́ lọ sí àpérò àgbáyé kẹfà ti àwọn Alàsọfọ̀ Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ní Geneva, tí ó wáyé láàárín ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n Oṣù Keje, ọdún 2025, kí ó tó tẹ̀síwájú sí Lọ́ńdọ̀nù fún ìsinmi kúkúrú kan.

Ààrẹ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin náà dé papa ọkọ̀ òfurufú Nnamdi Azikiwe International Airport, ní ìlú Abuja, ní nǹkan bí agogo mẹ́rin àárọ̀ ọjọ́ Àìkú, níbi tí àwọn Sẹ́nátọ̀, àti àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti oríṣìíríṣìí ibi ti gbà á lálejò ní ẹ̀ka ààrẹ.

Nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nígbà tí ó dé, Akpabio fún àwọn ará Nàìjíríà ní ìdánilójú pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn aṣòfin yóò lágbára sí i nígbà tí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin bá padà bẹ̀rẹ̀.

“Kò sí ohunkóhun bẹ́ẹ̀. Mo lágbára bíi ẹni tí ó mú dáadáa. Mo kàn dúró sí Lọ́ńdọ̀nù fún ìsinmi kúkúrú kan ni,” ni Akpabio sọ.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment