Awọn Afẹṣẹja Méjì Padanu Emi won Látàrí Ìpalára Ọpọlọ Nínu Eré Ìdárayá Kan Ní Tokyo
Àwọn Afeseja méjì ní orílẹ̀-èdè Japan ti kú látàrí ọgbẹ́ ọpọlọ tí wọ́n ní nínú àwọn ìjàkadì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà ìdíje kan náà ní Tokyo, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ ti sọ.
Shigetoshi Kotari tí ó jẹ́ akẹ́ṣẹ́ lightweight àti Hiromasa Urakawa, tí ó jẹ́ akẹ́ṣẹ́ lightweight, tí àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, jà ní ibi ere ese kan náà ní Tokyo’s Korakuen Hall ni oṣù kẹjọ, ọjọ́ kejì.
Wọ́n gbé àwọn méjèèjì lọ sí ilé-ìwòsàn lẹ́yìn náà níbi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ orí fún wọn.
Kotari, tí ó jà títí di ìbáradọ́gba lẹ́yìn ìgbà tí ó ti jà fún àkókò 12 lòdì sí akẹ́ṣẹ́ ará Japan, Yamato Hata, pàdánù ìmọ̀lára kété lẹ́yìn náà, ó sì “kú ni 10:59 ìrọ̀lẹ́ ni oṣù kẹjọ, ọjọ́ kẹjọ,” gẹ́gẹ́ bí M.T boxing gym ṣe sọ lórí ìkànnì wọn ní ọjọ́ Saturday.
Ìwé-ìkéde tí gbàjímu náà fi sílẹ̀ sọ pé, “Ó ṣe gbogbo ipa rẹ̀ láti kọjá nínú iṣẹ́ abẹ àti ìtọ́jú tí ó ti ń gbà ní ilé-ìwòsàn Tokyo nítorí àìsàn subdural haematoma.”
Wọ́n dá Urakawa dúró ní àkókò kẹjọ àti àkókò ìkẹyìn lòdì sí Yoji Saito, ó sì “kú ní ìbànújẹ́ nítorí àwọn ìfarapa tí ó gba ní àkókò ìjà rẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí World Boxing Organisation (WBO) ṣe sọ nínú ìwé-ìkéde kan lórí Instagram ni ọjọ́ Sunday.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn agbègbè ṣe sọ, Urakawa kú ni alẹ́ ọjọ́ Saturday.
WBO sọ pé, “Ìròyìn tó kún fún ìbànújẹ́ yìí wáyé ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ikú Shigetoshi Kotari, ẹni tí ó kú nítorí àwọn ìfarapa tí ó gba ní àkókò ìjà rẹ̀ ní ibi ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà,” ó sì fi kún un pé ó fi “ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó jinlẹ̀ hàn sí àwọn ìdílé, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn ìjọ akẹ́ṣẹ́ ti Japan”.
Akọ̀wé àgbà ti Japan Boxing Commission, Tsuyoshi Yasukochi, sọ fún àwọn ìwé ìròyìn agbègbè lẹ́yìn tí wọ́n ti gbé wọn lọ sí ilé-ìwòsàn pé ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ “ìgbà àkọ́kọ́ ní Japan tí àwọn akẹ́ṣẹ́ méjì ṣe iṣẹ́ abẹ orí fún àwọn ìfarapa tí ó wáyé láti ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà”.
Orisun – AFP
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua