Wọ́n yan Nnadozie àti Madugu fún àmì Ẹ̀yẹ Amule Tó Dárajùlọ àti Olùkọ́ni Àwọn Obìnrin tó Dárajùlọ fún Ballon d’Or

Last Updated: August 7, 2025By Tags: , ,

Wọ́n ti yan olùṣọ́lé Super Falcons ti Nàìjíríà, Chiamaka Nnadozie, àti olùkọ́ni Justine Madugu fún ìdíje Ballon d’Or ọdún 2025.

Wọ́n yan Nnadozie fún Women’s Yachine Trophy nígbà tí wọ́n yan Madugu fún akonimongba awon obirin ti o dara julo.

Olùṣọ́lé Brighton yìí wà lára àwọn obìnrin márùn-ún tí wọ́n yan, títí kan Ann-Katrin Berger ti Germany àti Gotham FC, Cata Coll ti FC Barcelona, Hannah Hampton ti England àti Chelsea, àti Daphne Van Domselaar ti Arsenal.

Asole Paris FC tẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ara ẹgbẹ́ Super Falcons tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ife eye Women’s Africa Cup of Nations lẹ́yìn tí wọ́n borí orílẹ̀-èdè tó gbà wọ́n lálejò, ìyẹn Morocco, 3-2 lẹ́yìn ìgbìyànjú dáradára níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìgbẹ̀yìn ní Rabat ní oṣù keje ọjọ́ kerindinlogbon, ọdún 2025.

Nnadozie ló di olùṣọ́lé tó dárajù lọ nínú ìdíje náà níbi tí Super Falcons ti gba àmì ẹ̀yẹ wọn kẹwàá.

Wọ́n yan Madugu, tó darí ẹgbẹ́ náà sí ìṣẹ́gun, fún Women’s Team Coach of the Year Trophy, pẹ̀lú

Àwọn mìíràn tí wọ́n tún yan nínú àkójọ náà ni Sonia Bompastor ti Chelsea, Arthur Elias ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti Brazil, Renée Slegers ti Arsenal, àti olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìnrin ti England, Sarina Wiegman.

Ìdánilójú Ballon d’Or kẹtàdínlọ́gọ́ta (69) yóò wáyé ní oṣù kẹsán ọjọ́ 22, ọdún 2025, ní Théâtre du Châtelet ní Paris, France.

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment