Àwọn Ìlànà Owó-ajé Lile Tinubu Ti Pa Àwùjọ Àwọn Araile Àárín Rẹ́ – Falana

Last Updated: August 4, 2025By Tags: , ,

Amòfin ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn, Femi Falana, ti ṣáátáwọ́ àwọn àtúnṣe ọrọ̀-ajé Ààrẹ Bola Tinubu, ó sì sọ pé àwọn “ìlànà àìbójútó owó-ajé” ti ìjọba náà ti pa àwọn kilasi alabọde ti Nigeria (middle class) run, ó sì ti mú ìgbésí ayé le fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà.

Falana sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ààrẹ ti gbà pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ń dojú kọ ìṣòro ọrọ̀-ajé, àwọn ìlànà rẹ̀ ti mú ipò òṣì burú sí i.

Ó sọ fún etò Channels Television’s Politics Today lọ́jọ́ Àje pé: “Mo ti rí i pé Ààrẹ ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Gómìnà APC láti ‘tún ilẹ̀ ṣe’ sí i, ṣùgbọ́n bí ó ṣe kan àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè, nǹkan ti ń le sí i lójoojúmọ́ nítorí àṣà ìṣòro ọrọ̀-ajé tó le, èyí tí Ààrẹ gbà pé àwọn ọmọ Nàìjíríà káàkiri orílẹ̀-èdè ń se ikunsinu pé nǹkan ń le si fún wọn.

Nítorí ṣíṣe ìlànà àìbójútó owó-ajé lọ́nà tó lé koko láti ọwọ́ ìjọba, òṣì ń gbòòrò sí i. Èyí yóò béèrè fún àtúnyẹ̀wò àwọn ìlànà wọ̀nyí.”

Amòfin Àgbà Nàìjíríà náà tako igbese ìjọba láti fi àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba fún àwọn ènìyàn lasan (privatisation), ó sọ pé ó tako àwọn ìsapá láti gbógun ti àìdọ́gba owó-èyí tí ó wọlé, ó sì fi kún un pé ìjọba gbọ́dọ̀ tún àwọn àfojúsùn rẹ̀ ṣe, kí ó sì pèsè ìrànlọ́wọ́ pàtàkì fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò lágbára, pàápàá àwọn tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè ìgbèríko.

Ó sọ pé: “Ẹ kò lè yanjú àìdọ́gba owó-èyí tí ó wọlé ní orílẹ̀-èdè kan nígbà tí ẹ bá ẹ̀ ń fi àwọn ohun àmúṣọrọ̀ orílẹ̀-èdè fún àwọn díẹ̀ lára àwọn ènìyàn lórúkọ ìfi-ilé-iṣẹ́-ìjọba-fún-àwọn-ènìyàn-lasan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Nàìjíríà kò lè rówó fún oúnjẹ mẹ́ta lójoojúmọ́.

Àwọn tí owó wọn wà ní àárín ti parẹ́ láti ọwọ́ àwọn ìlànà àìbójútó owó-ajé ti ìjọba. Ìjọba gbọ́dọ̀ padà sí ibi ìgbìmọ̀, kí wọ́n sì ṣe àtúnyẹ̀wò gbogbo àwọn ìlànà wọ̀nyí, pàápàá àwọn tí IMF àti World Bank ń tì, fún ànfààní àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ó wà fún ànfààní ìjọba láti ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ìlànà rẹ̀ kíákíá.”

Láti ìgbà tí ó ti dé ipò Ààrẹ ní Oṣù Karùn-ún 2023, Tinubu ti ṣègbékalẹ̀ àwọn àtúnṣe ọrọ̀-ajé tó gbòòrò, títí kan yíyọ owó kúrò ní ìṣàkóso ìjọba àti gbígbé owó ìrànlọ́wọ́ epo kúrò.

Ó sọ pé: “Láti fi òpin sí òṣì, a gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣe àwọn òfin ààbò ìgbé ayé,” ó tọ́ka sí National Social Investment Programme (NSIP), tí wọ́n fi sínú Òfin àjọ Social Investment Programme Agency Act ní 2023. “Ààrẹ Tinubu gbọ́dọ̀ lè rọ àwọn gómìnà láti fi àwọn ètò ìgbàkọ́lé owó sínú òfin, kí wọ́n sì ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí òfin,” ó sọ.

 

Orisun – Channels Tv

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment