Èmi ò rí ara mi gẹ́gẹ́ bí ọmọ Nàìjíríà – Kemi Badenoch
Olórí ẹgbẹ́ Conservative ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Kemi Badenoch, ti sọ pé òun kò ka ara rẹ̀ sí ọmọ Nàìjíríà mọ́, òun kò sì ní ìwé ìrìnnà (passport) Nàìjíríà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ètò Rosebud podcast tí Gyles Brandreth ń darí, Badenoch ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé rẹ̀ wá láti orile ede Nàìjíríà àti pé ó gbé ní orílẹ̀-èdè náà fún ìgbà díẹ̀ nígbà tó ṣì kéré, òun kò ka ara rẹ̀ sí ọmọ Nàìjíríà mọ́.
Ó sọ pé: “Èmi jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nípasẹ̀ ìdílé mi, nípasẹ̀ àwọn òbí mi, bò tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò bí mi síbẹ̀, ṣùgbọ́n nípa ìdánimọ̀, èmi kì í ṣe ọmọ Nàìjíríà ní tòótọ́.”
Mínísítà náà, tí wọ́n bí sí Wimbledon, London, ní ọdún 1980, sọ pé òun kò tíì tún ìwé ìrìnnà Nàìjíríà rẹ̀ ṣe fún ọdún tó ti lé ní ogún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wá láti ìdílé Nàìjíríà, ó tẹnu mọ́ ọn pé òun kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ sí orílẹ̀-èdè náà mọ́.
Ó fi kún un pé: “Mo mọ orílẹ̀-èdè náà dáadáa, mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé níbẹ̀, ọ̀rọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ sì ń jẹ mí lógún.”
Badenoch lo apá kan pàtàkì nínú ìgbà èwe rẹ̀ ní Nàìjíríà àti United States kó tó padà sí UK nígbà tó pé ọmọ ọdún merindinlogun. Ó wà lára àwọn ẹgbẹ́ ènìyàn tó gbẹ̀yìn láti gba ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú Gẹ̀ẹ́sì nípasẹ̀ ìbí kí ìlànà náà tó di fífagilé ní ọdún 1981 láti ọwọ́ ìjọba Margaret Thatcher.
Ó ròyìn lórí àwọn ìṣòro àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rántí pé: “Ohun tó le jù lọ tí mo gbọ́dọ̀ ṣe ni láti gbẹ́kẹ̀ lé ara mi nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mejidinlogun.”
Badenoch tún sọ ìmọ̀lára rẹ̀ nípa bí kò ṣe fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ sí Nàìjíríà nígbà tó ń gbé níbẹ̀, ó sọ pé: “N kò tíì fi bẹ́ẹ̀ rò pé mo jẹ́ ti ibẹ̀ pátápátá.”
Báyìí, tí ó ti fi ìdí kalẹ̀ ní UK, ó ṣàpèjúwe ohun tí “ilé” túmọ̀ sí fún òun lónìí.
Ó sọ pé: “Ṣùgbọ́n ilé ni ibi tí ìdílé mi wà báyìí, ìdílé mi báyìí sì ni àwọn ọmọ mi, ọkọ mi, àti arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ìbátan mi. Ẹgbẹ́ Conservative jẹ́ apá pàtàkì nínú ìdílé mi, ìdílé mi tó gbòòrò, mo pè é.”
Lórí àkópọ̀ ọmọ ìlú rẹ̀, ó sọ pé: “Gbígbàgbé pé mo ní ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú Gẹ̀ẹ́sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi.”
Orisun- Vanguard
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua