Ààrẹ Tinubu Yan Adeyemi gẹ́gẹ́ Bíi Olórí Tuntun fún Ẹ̀ka Panapaná

Last Updated: July 30, 2025By Tags: , ,

Ààrẹ Bola Tinubu ti fọwọ́ sí yíyàn DCG Olumode Samuel Adeyemi gẹ́gẹ́ bíi Adarí-Àgbà (Controller-General) tuntun ti Ẹ̀ka Tó Ń Pa Ina ní Ìjọba Àpapọ̀ (Federal Fire Service – FFS).

Ìyàn náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Kẹjọ, ọdún 2025.

Ìwé ìkéde ìyàn náà jáde láti ọwọ́ Ìgbìmọ̀ Civil Defence, Correctional, Fire and Immigration Services Board (CDCFIB), tí akọ̀wé rẹ̀, Abdulmalik Jibrin fọwọ́ sí.

Ìwé ìkéde náà sọ pé ìyàn yìí wáyé nítorí pé Adarí-Àgbà lọ́wọ́lọ́wọ́, Engr. Abdulganiyu Jaji Olola, yóò fẹ̀yìn tì ní Ọjọ́ kinni oṣù Kẹjọ, ọdún 2025, lẹ́yìn tí ó bá ti pé ọmọ ọdún ọgọ́ta.

DCG Olumode Samuel Adeyemi ní irírí púpọ̀ nínú iṣẹ́ tuntun rẹ̀. Ó ti gbé iṣẹ́ rẹ̀ wá láti Ẹ̀ka Tó Ń Gbẹ́ Iná Jẹ ti FCT sí Federal Fire Service, ó sì ti gun ipò dé Deputy Controller-General of Fire ní Àjọ Rírí Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba (Human Resource Directorate) ní Ilé-iṣẹ́ Àkọ́kọ́ ti Ẹ̀ka náà.

Nígbà iṣẹ́ rẹ̀, òṣìṣẹ́ náà ti lọ gbogbo àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó jẹ́ dandan nínú iṣẹ́, àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìdarí, àti àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn nínu àti lóde orílẹ̀-èdè.

Ó ti ṣiṣẹ́ ní oríṣìíríṣìpò ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tàbí alábàákẹ́gbẹ́ àwọn àjọ amọṣẹ́dáwé wọ̀nyí: Association of National Accountants of Nigeria (ANAN), Institute of Corporate Administration of Nigeria, Institute of Public Administration of Nigeria, àti Chartered Institute of Treasury Management of Nigeria.

Ìgbìmọ̀ náà fi ọpẹ́ rẹ̀ hàn sí Adarí-Àgbà tí ó fẹ̀yìn tì, Engr.

Abdulganiyu Jaji Olola, fún àwọn ìkópa rẹ̀ tó yẹ fún ìyìn nínú ìdàgbàsókè Federal Fire Service. Wọ́n tún gbóríyìn fún ìfọkànsí rẹ̀ sí iṣẹ́ náà, àti àwọn ìgbésẹ̀ púpọ̀ tí ó ṣe àkóso rẹ̀ nígbà iṣẹ́ rẹ̀.

Orisun- Vangaurd

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment