Henderson Ti Pari Ipadabọ Rẹ Si Premier League Pẹlu Lilọ Si Brentford
Lẹ́yìn àkókò tí ó lò ní Saudi Arabia àti Netherlands, Jordan Henderson ti padà sí Premier League lẹ́yìn tí ó darapọ̀ mọ́ Brentford.
Jordan Henderson ti padà sí Premier League lẹ́yìn tí ó ti parí ifọwọsiwe rẹ si Brentford.
Ọmọ orílẹ̀-èdè England náà ti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn ọdún méjì pẹ̀lú The Bees, ó sì ti dé Gtech Community Stadium láìsanwolẹ́yìn tí ó kúrò ní Ajax ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yìí.
Henderson kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ Premier League rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọdún 18 pẹ̀lú Sunderland ṣáájú kí ó tó lọ si Liverpool ni ọdún 2011.
Ó wá di balógun The Reds ni ọdún 2015, ó sì gbé àwọn ife mẹ́jọ (8), nínú èyí tí ó wà Champions League àti Premier League.
Agbá-bọ́ọ̀lù àárín gbùngbùn náà lo sáà kan pẹ̀lú Al-Ettifaq ṣáájú kí ó tó darapọ̀ mọ́ Ajax ní Eredivisie ní ọdún 2024.
Láàárín àkókò rẹ ní Premier League, Henderson ti gbá bọ́ọ̀lù ní (431) ìgbà, ó sì ti gbá bọọlu wọnu awọn ni igba 33 ó sì ti pese àwọn ìrànlọ́wọ́ 53.
Ó ti farahàn ní mẹrinlelọgọrin (84) ìgbà fún orílẹ̀-èdè rẹ̀, wọ́n sì yan án gẹ́gẹ́ bí England Senior Men’s Player of the Year ni ọdún 2019.
Níwọ̀n bí Brentford ti pàdánù balógun ẹgbẹ́, Christian Norgaard, sí Arsenal ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò saa yìí, àṣáájú Henderson lè jẹ́ àfikún pàtàkì.
Olùkọ́ agbá-bọ́ọ̀lù Brentford, Keith Andrews, sọ fún àwọn oníròyìn ẹgbẹ́ náà pé: “Nígbà tí a mọ̀ pé Henderson wà nílẹ̀, ìpinnu kan náà ni.
“A ṣe ìwádìí wa dáadáa nípa àwọn bọọlu rẹ̀ àìpẹ́ yìí láti mọ ipò rẹ̀: ó ṣì lágbára gan-an, ó sì ní ìtara láti ṣàṣeyọrí nínú eré náà, lẹ́yìn tí ó ti ṣàṣeyọrí púpọ̀.
“Pẹ̀lú àìsí àwọn agbá-bọ́ọ̀lù olókìkí tó fi ilé náà sílẹ̀ – Christian Norgaard, Mark Flekken àti Ben Mee – ó ṣe pàtàkì láti rọ́pò wọn.
“Ṣùgbọ́n ohun tí Jordan yóò mú wá ni pé ó ti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn aṣáájú tó ní ipa jù lọ ní àwọn ọdún Premier League òde òní. Ó ti jẹ́ olùdáṣáájú nígbà tí wọ́n ń lé àwọn ife àti Champions League ní ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù tó dára jù.”
Brentford yóò bẹ̀rẹ̀ ìpolongo 2025-26 wọn ní ilé Nottingham Forest ní Oṣù Kẹjọ ọjọ́ kẹtàdínlógún, Henderson yóò sì dojú kọ Sunderland, ẹgbẹ́ àtijọ́ rẹ̀ ní Stadium of Light ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà.
Ọmọ ọdún 35 náà yóò ní àǹfààní láti gbá bọ́ọ̀lù lòdì sí Liverpool fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí ó ti fi Anfield sílẹ̀ ní Oṣù Kẹwa ọjọ́ kẹẹẹdọ́gbọ̀n nígbà tí wọ́n bá kọlu ẹgbẹ́ Arne Slot ní ilé.
Ṣé o fẹ́ mọ nkan mìíràn nípa gbigbe Jordan Henderson si Brentford?
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua