Luka Modrić Dágbére Fún Real Madrid!
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní Madrid, Olubori Ballon d’Or àti ògbóǹkangí agbábọ́ọ̀lù Luka Modric Luka Modric, ti pinnu láti tẹ̀síwájú sí ìpele tó kàn ní bọọlu ní ẹ̀ka ìdíje mìíràn.

Luka Modrić played his final game for Real Madrid on Wednesday. Marvin Ibo Guengoer – GES Sportfoto-Getty Images
Luka Modrić ti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn ọdún kan pẹ̀lú AC Milan tó wúlò títí di oṣù June ọdún 2026, ó sì dé lẹ́yìn ìdíje Club World Cup gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣètò rẹ̀.
Agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Croatia, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógójì [39] yìí, ti gbá bọ́ọ̀lù fún Real Madrid láti ọdún 2012 títí di ìgbà yìí, nínú èyí tó ti gbá eré 394, tó sì ti gba àmi ayò 30 wọlé fún ẹgbẹ́ náà.
Ẹni tó gba àmì-ẹ̀yẹ Ballon d’Or ti ọdún 2018 yìí ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ pẹ̀lú Real Madrid, títí kan Champions League, Copa Del Rey, Club World Cup, La Liga àti àwọn àmì-ẹ̀yẹ abẹ́lé mìíràn.
Agbábọ́ọ̀lù tó ní ẹ̀bùn yìí ti darapọ̀ mọ́ AC Milan lẹ́yìn tó gbá eré rẹ̀ tó kẹ́yìn fún Madrid lánàá, yóò sì gbá bọ́ọ̀lù fún ọdún kan nínú ìdíje Serie A.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua