Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Ọba Olákulehin, ti fi ayé sílẹ̀, O Si Ti Darapọ̀ Mọ́ Awọn Bàbá Nlá Rẹ̀.
Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Owolabi Olakulehin, ti fi ayé sílẹ̀, ó sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn bàbá ńlá rẹ̀.
Tribune Online gbéyẹ̀wò pé ọba náà, tí ó jẹ́ oyè ní oṣù Keje ọdún 2024, kú ní òwúrọ̀ kutukutu Ọjọ́ Ajé, oṣù Keje ọjọ́ Keje, ọdún 2025, lẹ́yìn tó lo ọdún kan péré lórí ìtẹ́.
Ikú Ọba Olákulehin, tí wọ́n bí ní oṣù Keje ọjọ́ 5, ọdún 1935, wáyé ní kété lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ó ṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí rẹ̀ tó pé Àádọ́rùn-ún (90 years) ọdún.
Gẹ́gẹ́ bí Tribune Online ti ròyìn, Ọba Olákelehin gbà ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ, Engr. Seyi Makinde, ní oṣù Keje ọjọ́ 12, ọdún 2024, gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn kẹtàlélọ́gbọ̀n (43rd) ilẹ̀ Ìbàdàn.
Ọba Olákulehin wọlé sípò ọba láti ipò Balógun Olúbàdàn, lẹ́yìn ikú Ọba (Dr.) Moshood Lekan Balogun, Alli Okunmade II, tó kú ní ọmọ ọdún mọ́kànlelọ́gọ́rin (81) ní oṣù Kẹta ọjọ́ 14, ọdún 2024.
Orísun: Tribune
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua