An aerial view of the flooding near Kerrville, Texas. Pic: US Coast Guard via Reuters

Àwọn aláṣẹ Ilẹ̀ ti Fèsì sí Ikún Omi tó Wáyé ní Texas

Last Updated: July 6, 2025By Tags: , ,

Ìròyìn BBC sọ pé, ó kéré tán, èèyàn mọ́kànléláàádọ́ta ló ti kú nítorí omíyalé tó wáyé ní Texas, lára wọn ni àwọn ọmọdé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Bí àwárí àwọn tí wọ́n sọnù ṣe ń tẹ̀síwájú, ààrẹ àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń fèsì sí ìkún omi tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní Texas.

Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump, kò tíì sọ̀rọ̀ lónìí, ṣùgbọ́n lánàá ó sọ pé ìjọba òun ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ tí ó wà ní Texas láti fèsì sí ìkún omi burúkú tí ó ṣẹlẹ̀.

Ọ̀gá Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ààbò Ilẹ̀ Kristi Noem sọ pé “ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí àwọn èèyàn wà láàyè” ó sì ṣèlérí pé àwọn ọkọ̀ òfuurufú tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń wá ibi tí wọ́n ti lè rí i gbà á máa pọ̀ sí i.

Gómìnà Texas Greg Abbott fi dá àwọn ẹbí tó ń ṣàníyàn lójú pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ kò ní dáwọ́ dúró àyàfi tí iṣẹ́ náà bá parí.

 Texas Governor, Greg Abbott

Gómìnà Texas, Greg Abbott sọ pé òun ti fọwọ́ sí ìkéde àjálù tí a mú gbòòrò láti mú kí ìsapá ìwárí pọ̀ sí i: EPA

Àwa tún ti gbọ́ ìfèsì láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí orílẹ̀-èdè pataki

Pópù Leo XIV, ẹni tí wọ́n bí sí Amẹ́ríkà, ti fi ìwé ránṣẹ́ sí orí ìkànnì ayélujára,ó ń bá gbogbo ìdílé tó pàdánù àwọn olólùfẹ́ wọn kẹ́dùn, ní pàtàkì àwọn ọmọbìnrin wọn, tí wọ́n wà ní ibùdó ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn náà”.

Pople leo XIV

Pópù Leo XIV ti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Reuters

Ààrẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky, fi ìbánikẹ́dùn rẹ̀ ránṣẹ́ sí Trump, ó sì sọ pé òun nírètí pé “àwọn tí wọ́n sọnù, títí kan àwọn ọmọdé láti àgọ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, yóò padà sí ibi ààbò ní kíákíá”.

Prime Minister India, Narendra Modi, sọ pé òun “bànújẹ́ púpọ̀” nígbà tó gbọ́ nípa ìpàdánù ẹ̀mí ní Texas.

 

Orisun: BBCNEWS

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment