Peter Rufai, Agbábọ́ọ̀lù Tẹ́lẹ̀ Tí Ti Super Eagles, ti dagbere faye
DODOMAYANA DAGBERE FAYE
Peter Rufai, tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó máa ń gbèjà (goalkeeper) fún Super Eagles tẹ́lẹ̀ rí, ti kùú. Waidi Akanni, tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, fìdí ikú gbajúmọ̀ ati ogbontarigi agbábọ́ọ̀lù náà múlẹ̀ ní Ọjọ́bọ̀ (Thursday)
Rufai, tí orúkọ àpèlé rẹ̀ jẹ́ Dodo Mayana, kú nígbà tó pé omo ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta (61) lẹ́yìn ìjàkadì pẹ̀lú àìsàn pípẹ́.
Super Eagles ti Nàìjíríà náà kéde ikú agbábọ́ọ̀lù àtijọ́ náà lórí àkọọ́lẹ̀ X ti ẹgbẹ́ náà. Ìfìwéránṣẹ́ náà kà pé: “Títí láé nínú ọkàn wa, Dodo Mayana. A ń dárò ikú gbajúmọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles, Peter Rufai, tí ó jẹ́ òrìṣà nínú eré bọ́ọ̀lù afeesegba Nàìjíríà, tí ó sì jẹ́ aṣíwájú ninu idije AFCON ọdún 1994.”
Wọ́n ka Rufai sí ọ̀kan nínú àwọn agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ tí Nàìjíríà tíì ní. Ó jẹ́ olùṣọ́ góòlù àkọ́kọ́ fún àwọn Eagles nígbà tí Nàìjíríà gba ife ẹ̀yẹ nínú Africa Cup of Nations (AFCON) ọdún 1994.
editor's pick
latest video
news via inbox
Nulla turp dis cursus. Integer liberos euismod pretium faucibua