Bali

Àwọn mẹ́fà ti padanu emi won, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sọnù nígbà tí ọkọ̀ ojú omi kan rì ní Bali

Last Updated: July 3, 2025By Tags: , ,

Ó kéré tán èèyàn mẹ́fà ló ti pádànù ẹ̀mí wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì ti sọnù lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi kan rì ní erékùṣù Bali tí àwọn arìnrìn-àjò ń wọ lọ si Indonesia, àwọn olùgbàlà sọ bẹ́ẹ̀.

Ọkọ̀ náà ń gbé àwọn arìnrìn-àjò metalelaadọta  àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀ méjìlá nígbà tí ó rì sínú omi ní 23:20 àkókò àdúgbò (15:35 GMT) ní Ọjọ́rú nígbà tí ó ń lọ sí Bali láti Banyuwangi ní etíkun ìlà oòrùn erékùṣù Java, ọ́fíìsì Surabaya ti National Search and Rescue Agency sọ.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà sọ pé, àwọn èèyàn mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni wọ́n ti rí tí wọ́n sì gbà là, bí ìwádìí náà ṣe ń bá a lọ. Àmọ́, àwọn ìròyìn mélòó kan fi hàn pé àwọn arìnrìn-àjò tó wà nínú ọkọ̀ náà lè ju iye tí wọ́n kọ sínú àkọsílẹ̀ àwọn arìnrìn-àjò lọ.

Àwọn aláṣẹ ń ṣe ìwádìí lórí ohun tó fa ìjì náà.

BBC ti bá àwọn ẹbí àwọn tó kú sọ̀rọ̀, wọ́n sọ pé orúkọ àwọn ìbátan wọn kò sí lára àwọn márùndínláàádọ́rin tí wọ́n kọ sínú àkọsílẹ̀ àwọn arìnrìnàjò.

Lórílẹ̀-èdè Indonesia, ọ̀pọ̀ ìgbà ni iye àwọn èrò tó wà nínú ọkọ̀ ojuomi kì í bá iye tí wọ́n kọ sílẹ̀ mu, èyí sì máa ń mú kí iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ṣòro, ó sì máa ń jẹ́ kó ṣòro láti mọ àwọn tó kú.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó là á já jẹ́ olùgbé ìlú Banyuwangi tó wà létíkun nígbà tí àwọn mìíràn wá láti àwọn agbègbè tó wà ní ààrin Java, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tí àwọn aláṣẹ gbé jáde.

Imron, olùgbé Banyuwangi, sọ pé ọkọ̀ ojú omi náà yára rì lẹ́yìn tí ó ti rọra yí padà ní ìgbà mẹ́ta. Ó sọ pé: “Nígbà tó fi máa di ìgbà kẹta, omi òkun ti wọ inú ọkọ̀ náà.

Imron lúwẹ̀ẹ́ gba àlàfo kan nínú ọkọ̀ ojú omi náà, ó sì lọ sí òkun, kó tó di pé ó rí aṣọ ààbò. Nígbà tó yá, apẹja kan wá gbà á sílẹ̀.

Bejo Santoso, ti orí kóyọ nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi náà, sì rí aṣọ tí wọ́n fi ń gba ẹ̀mí èèyàn là mú.

 

BBC

BBC

“Ní nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ta lẹ́yìn tí ọkọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ, ó rì. Mo ṣì ní àkókò láti fò, “ó sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Antara ti Indonesia.

Ààrẹ Prabowo Subianto ti pàṣẹ fún ìdáhùn pàjáwìrì láti Saudi Arabia, níbi tí ó ti ń ṣe àbẹ̀wò ìjọba.

Ọ̀nà tí ọkọ̀ òkun náà gbà, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó gbajúmọ̀ jù lọ ní Indonesia, làwọn ará àdúgbò sábà máa ń gbà lọ láàárín erékùṣù Java àti Bali.

 

Orísun: BBC NEWS

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment