mtn and 9mobile

9Mobile Ti Ṣe Ifowosowopo Pẹlu MTN Lati Mu Ibaraẹnisọrọ Dara Si

9Mobile Ti Ṣe Ifowosowopo Pẹlu MTN Lati Mu Ibaraẹnisọrọ Dara Si

Ajọ to n ṣakoso ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, Nigerian Communications Commission (NCC), ti fọwọsi adehun tuntun kan ti yoo jẹ ki awọn onibara 9Mobile le lo nẹ́wọ̀ọ̀kì MTN nigba ti nẹ́wọ̀ọ̀kì 9Mobile ko si.

Adehun yii, ti yoo wulo fun ọdun mẹta, ni a ṣe lati mu iraye si ibaraẹnisọrọ dara si, paapaa ni awọn agbegbe igberiko ati awọn ilu kekere ti n jiya lati aini nẹ́wọ̀ọ̀kì.

Nipasẹ adehun naa, diẹ̀ sii ju eniyan miliọnu 2.8 ti n lo 9Mobile ni yoo ni anfani lati gba iraye si nẹ́wọ̀ọ̀kì MTN lai ni lati ra SIM tuntun. Wọn yoo tun maa sanwo gẹgẹ bi oṣuwọn 9Mobile wọn, paapaa bi wọn ti n lo nẹ́wọ̀ọ̀kì MTN.

Eyi tumọ si pe awọn eniyan ni awọn agbegbe bii Ariwa ati Guusu-guusu, ti n dojukọ isoro asopọ, yoo ni anfani lati gbadun iṣẹ ibaraẹnisọrọ to yara, ailopin awọn ipe ti n ya, ati agbara lati lo SIM kan ṣoṣo ni gbogbo irin-ajo wọn.


Kilode Ti 9Mobile Fi Nilo Eleyi

Ṣaaju, 9Mobile jẹ́ ile-iṣẹ to n dagba ni kiakia, ṣugbọn bayi o ti ṣubu lọpọlọpọ. Lati eniyan miliọnu 13, o ti ṣubu si bii miliọnu 3.4, to jẹ́ 2.15% ninu ọja nẹ́wọ̀ọ̀kì Naijiria. Awọn iṣoro bii gbese, iyipada oniwun, ati iṣẹ ti ko dara lo fa ki awọn onibara bẹrẹ si fi ile-iṣẹ naa silẹ.

Pẹlu adehun roaming yii, 9Mobile le tun ni igboya lati fi iṣẹ to dara han ati da awọn onibara to n lọ duro, lai ni lati fi owo nla ṣe amugbalẹgbẹ lori ẹrọ nẹ́wọ̀ọ̀kì tuntun.

Anfaani Fun MTN ati NCC

MTN, ti o ni ẹni to ju miliọnu 90 lọ gẹgẹ bi onibara, yoo fi awọn nẹ́wọ̀ọ̀kì to ti ni tẹlẹ jẹ orisun owo tuntun, laisi dẹkun iṣowo rẹ. Ile-iṣẹ naa ti pẹ ti n pe ohun ti wọn nṣe yii ni “network-as-a-service”—ẹ̀rọ nẹ́wọ̀ọ̀kì bii iṣẹ́, kàkà ki wọn maa ra awọn ile-iṣẹ miran.

NCC naa n wo ohun gbogbo yii gẹgẹ bii ọna lati mu ibaraẹnisọrọ de gbogbo eniyan, lai fa ija owo kekere to le ba awọn ile-iṣẹ jẹ. Ninu ọdun 2020, wọn ti ṣe idanwo roaming laarin MTN ati 9Mobile ni ipinlẹ Ondo, ati bayi wọn fẹ ki gbogbo awọn ile-iṣẹ miran tun bẹrẹ lati ṣiṣẹ pọ.

Fun ọpọlọpọ eniyan ni Naijiria, paapaa ni ibi ti nẹ́wọ̀ọ̀kì ko ti de, adehun yii tumọ si aye tuntun lati pe, fi owo ranṣẹ, wọ̀lé si ẹ̀kọ́ ori ayelujara, ati ṣọ̀rọ̀ lai ni ki ipe yá.

Fun 9Mobile, eyi le jẹ igbesẹ pataki lati pada bọ sinu ifigagbaga—nibi ti agbara nẹ́wọ̀ọ̀kì jẹ koko pataki lati yege.

 

 

 

 

Source: TechPoint

editor's pick

latest video

Mail Icon

news via inbox

Nulla turp dis cursus. Integer liberos  euismod pretium faucibua

Leave A Comment